Amos 8:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo yí àsè àjọ̀dún yín pada sí ọ̀fọ̀, n óo sọ orin yín di ẹkún; n óo sán aṣọ ìbànújẹ́ mọ́ gbogbo yín nídìí, n óo sì mú kí orí gbogbo yín pá; ẹ óo dàbí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo, ọjọ́ náà yóo korò ju ewúro lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si yi àse nyin padà si ọ̀fọ, ati orin nyin gbogbo si ohùn-rére ẹkún: emi o si mu aṣọ ọ̀fọ wá si ẹgbẹ̀ gbogbo, ati pipá ori, si gbogbo ori; emi o si ṣe e ki o dàbi iṣọ̀fọ fun ọmọ kanṣoṣo ti a bi; ati opin rẹ̀ bi ọjọ kikorò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmí yóò yí àsè ẹ̀sìn yín padà sí ọ̀fọ̀, gbogbo orin yín ni èmi yóò sọ di ẹkún. Èmi yóò mú kí gbogbo yín wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí a sì fá orí i yín. Èmi yóò mú kí ìgbà náà rí bí ìṣọ̀fọ̀ fún ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí a bí àti opin rẹ̀ bí ọjọ́ kíkorò.