Amos 8:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ní, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí n óo rán ìyàn sí ilẹ̀ náà; kì í ṣe ìyàn, oúnjẹ, tabi ti omi, ìran láti ọ̀dọ̀ OLUWA ni kò ní sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa Ọlọrun wi, emi o rán iyàn wá si ilẹ na, kì iṣe iyàn onjẹ, tabi ongbẹ fun omi, ṣugbọn iyàn gbigbọ́ ọ̀rọ Oluwa:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLÚWA Ọlọ́run wí, “nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà, kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òùngbẹ fún omi. Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA.