Amos 8:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA bèèrè pé, “Amosi, kí ni ò ń wò yìí?” Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ni.” OLUWA bá sọ pé: “Òpin ti dé sí Israẹli, àwọn eniyan mi, n kò sì ní fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wipe, Amosi, kili ohun ti iwọ ri? Emi si wipe, Agbọ̀n eso ẹrùn ni. Nigbana li Oluwa wi fun mi pe, Opin de si Israeli enia mi; emi kì yio tún kọja lọdọ wọn mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó béèrè pé, “Ámósì kí ni ìwọ rí.” Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso pípọ́n.” Nígbà náà ni OLÚWA wí fún mi pé, “Àsìkò náà pọ́n tó fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì; Èmi kì yóò dá wọn sí mọ́.”