Amos 9:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo rí OLUWA, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, ó pàṣẹ pé, “Lu àwọn òpó tẹmpili títí tí gbogbo àtẹ́rígbà rẹ̀ yóo fi mì tìtì, tí yóo sì wó lé gbogbo àwọn eniyan lórí. N óo jẹ́ kí ogun pa àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù lára wọn, Kò ní sí ẹyọ ẹnìkan ninu wọn tí yóo lè sálọ, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ẹnìkan tí yóo sá àsálà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
MO ri Oluwa o duro lori pẹpẹ: o si wipe, Lù itẹrigbà ilẹ̀kun, ki awọn òpo ki o le mì: si ṣá wọn li ori, gbogbo wọn; emi o si fi idà pa ẹni ikẹhìn wọn: ẹniti o sá ninu wọn, kì yio salọ gbe; ati ẹniti o sa asalà ninu wọn li a kì yio gbàla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo rí OLÚWA, ó dúró ní ẹ̀bá pẹpẹ, ó sì wí pé: “Lu orí àwọn àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn kí àwọn òpó kí ó lè mì fọ́ wọn sí orí àwọn gbogbo ènìyàn àwọn tí ó sẹ́kù ni èmi yóò fi idà pa, Ẹni tí ó sálọ nínú wọn kí yóò sá gbé Ẹni ti ó sá àsálà nínú wọn kí yóò gbàlà.