Amos 9:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣẹgun àwọn tí wọ́n kù ní Edomu, ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí à ń fi orúkọ mi pè. Èmi OLUWA, tí n óo ṣe bí mo ti wí, èmi ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki nwọn le ni iyokù Edomu ni iní, ati ti gbogbo awọn keferi, ti a pè nipa orukọ mi, li Oluwa ti o nṣe eyi wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kí wọn le jógun ìyókù Édómù àti gbogbo orílẹ̀ èdè ti ń jẹ́ orúkọ mi,” ni OLÚWA, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí.