Amos 9:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ọjọ́ ń bọ̀, tí ọkà yóo so jìnwìnnì, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè kórè rẹ̀ tán kí àkókò gbígbin ọkà mìíràn tó dé. Ọgbà àjàrà yóo so, tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè fi ṣe waini tán kí àkókò ati gbin òmíràn tó dé. Ọtí waini dídùn yóo máa kán sílẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, ọtí waini yóo sì máa ṣàn jáde lára àwọn òkè kéékèèké.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa wi, ti ẹniti ntulẹ yio le ẹniti nkorè bá, ati ẹniti o ntẹ̀ eso àjara yio le ẹniti o nfunrùgbin bá; awọn oke-nla yio si kán ọti-waini didùn silẹ, gbogbo oke kékèké yio si di yiyọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọjọ́ náà ń bọ,” ni OLÚWA wí, “Tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀ Tí yóò sì ṣàn láti ara àwọn òkè kékèké.