Amos 9:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo dá ire Israẹli, àwọn eniyan mi, pada, wọn yóo tún àwọn ìlú tí wọ́n ti wó kọ́, wọn yóo sì máa gbé inú wọn. Wọn yóo gbin àjàrà, wọn yóo sì mu ọtí waini rẹ̀. Wọn yóo ṣe ọgbà, wọn yóo sì jẹ èso rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si tun mu igbèkun Israeli enia mi padà bọ̀, nwọn o si kọ́ ahoro ilu wọnni, nwọn o si ma gbe inu wọn; nwọn o si gbin ọgbà-àjara, nwọn o si mu ọti-waini wọn; nwọn o ṣe ọgbà pẹlu, nwọn o si jẹ eso inu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Ísírẹ́lì ènìyàn mi padà bọ̀ Wọn yóò sì kọ́ ahoro ìlú, wọn yóò sì máa gbé inú wọn Wọn yóò sì gbin àjàrà, wọn yóò sì mu ọtí wáìnì wọn wọn yóò sì se ọgbà pẹ̀lú, wọn yóò sì jẹ èso inú wọn