Amos 9:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, òun ló fọwọ́ kan ilẹ̀, tí ilẹ̀ sì yọ́, tí gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, tí gbogbo nǹkan ru sókè bí odò Naili, tí ó sì lọ sílẹ̀ bí odò Naili ti Ijipti;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li ẹniti o si fi ọwọ́ kan ilẹ na, yio si di yiyọ́, gbogbo awọn ti o ngbe inu rẹ̀ yio si ṣọ̀fọ: yio si rú soke patapata bi kikun omi: a o si tẹ̀ ẹ ri, bi odò Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA, Ọlọ́run Alágbára Ẹni ti ó fi ọwọ́ kan ìlẹ̀ náà tí ó sì yọ́, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì sọ̀fọ̀ Gbogbo orílẹ̀ èdè yóò si ru sókè bí ríru odò Náìlì ti wọn yóò sì tẹ̀rì bí odò Éjíbítì.