Amos 9:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA tí ó kọ́ ilé gíga rẹ̀ sí ojú ọ̀run, tí ó gbé awọsanma lé orí ilẹ̀ ayé tí ó pe omi òkun jáde, tí ó sì dà á sórí ilẹ̀, OLUWA ni orúkọ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On li ẹniti o kọ́ itẹ́ rẹ̀ ninu awọn ọrun, ti o si fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ ni ilẹ aiye: ẹniti o pè awọn omi okun, ti o si tú wọn jade si ori ilẹ aiye: Oluwa li orukọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun ni ẹni tí ó kọ́ itẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run ti ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ ní ilé ayé Ẹni ti ó pe àwọn omi òkun ti ó sì tú wọn jáde si orí ilé ayé OLÚWA ni orúkọ rẹ̀.