Amos 9:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun ní, “Ṣebí bí ẹ ti jẹ́ sí mi ni àwọn ará Etiopia náà jẹ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Àbí kì í ṣe bí mo ti mú àwọn ará Filistia jáde láti ìlú Kafitori, tí mo mú àwọn Siria jáde láti ìlú Kiri, ni mo mú ẹ̀yin náà jáde láti Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin kò ha dàbi awọn ọmọ Etiopia si mi, Ẹnyin ọmọ Israeli? li Oluwa wi. Emi kò ha ti mu Israeli goke ti ilẹ Egipti jade wá? ati awọn Filistini lati ilẹ Kaftori, ati awọn ara Siria lati Kiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àbá ẹyin ọmọ Ísírẹ́lì kò ha dàbí àwọn ọmọ Kúsì sí mi?” ni OLÚWA wí. “Èmi kò ha ti mú Ísírẹ́lì gòkè láti ilẹ̀ Éjíbítì jáde wá àti àwọn Fílístínì láti ilẹ̀ Káfítórì àti àwọn Árámú láti kírì?