Colossians 3:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kí ẹ máa fi gbogbo ọgbọ́n kọ́ ara yín, kí ẹ máa fún ara yín ní ìwúrí nípa kíkọ Orin Dafidi, ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá. Ẹ máa kọrin sí Ọlọrun pẹlu ọpẹ́ ninu ọkàn yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ jẹ ki ọ̀rọ Kristi mã gbé inu nyin li ọ̀pọlọpọ ninu ọgbọ́n gbogbo; ki ẹ mã kọ́, ki ẹ si mã gbà ara nyin niyanju ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã fi ore-ọfẹ kọrin li ọkàn nyin si Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kírísítì máa gbé inú yín lí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ sì máa gba ara yín, níyànjú nínú Sáàmù, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa fi oore ọ̀fẹ́ kọrin ní ọkàn yín sí Olúwa