Colossians 4:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Jusitu náà ki yín. Àwọn yìí nìkan ni wọ́n kọlà ninu àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ ìjọba Ọlọrun. Ìtùnú ni wọ́n jẹ́ fún mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Jesu, ẹniti a npè ni Justu, ẹniti iṣe ti awọn onila. Awọn wọnyi nikan ni olubaṣiṣẹ mi fun ijọba Ọlọrun, awọn ẹniti o ti jasi itunu fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti Jésù, ẹni tí à ń pè ní Jọsítọ́sì, ẹni tí ń ṣe ti àwọn onílà. Àwọn wọ̀nyí nìkan ni olùbá ṣiṣẹ́ mí fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn ẹni tí ó tí já sí ìtùnú fún mi.