Colossians 4:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìkíni tí èmi Paulu fi ọwọ́ ara mi kọ nìyí. Ẹ ranti pé ninu ẹ̀wọ̀n ni mo wà. Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹlu yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ikíni nipa ọwọ́ emi Paulu. Ẹ mã ranti ìde mi. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu nyin. Amin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìkíni láti ọwọ́ èmi Pọ́ọ̀lù. Ẹ máa ránti ìdè mi. Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹ̀lú yín. Àmín. A kọ ọ́ láti Rómù lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Kólósè láti ọwọ́ Tíkíkù àti Ónísímù.