Colossians 4:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Tukikọsi, àyànfẹ́ ati arakunrin wa, yóo fun yín ní ìròyìn nípa mi. Iranṣẹ tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ati ẹrú bí àwa náà ninu iṣẹ́ Oluwa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo bi nkan ti ri fun mi ni Tikiku yio jẹ́ ki ẹ mọ̀, arakunrin olufẹ ati olõtọ iranṣẹ, ati ẹlẹgbẹ ninu Oluwa:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikíkú yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀ gbogbo bí nǹkan tirí nípa mi. Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòótọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa: