Daniel 1:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Aṣipenasi sọ fún Daniẹli, pé, ẹ̀rù ń ba òun, kí ọba tí ó ṣètò jíjẹ ati mímu Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ má baà lọ ṣe akiyesi pé Daniẹli rù ju àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ, kí òun má baà fi ẹ̀mí òun wéwu lọ́dọ̀ ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olori awọn iwẹfa si wi fun Danieli pe, Mo bẹ̀ru ọba, oluwa mi, ẹniti o yàn onjẹ nyin ati ohun mimu nyin: nitori bawo li on o ṣe ri oju nyin ki o faro jù ti awọn ọmọkunrin ẹgbẹ nyin kanna lọ? nigbana li ẹnyin o ṣe ki emi ki o fi ori mi wewu lọdọ ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ fún Dáníẹ́lì pé, “Mo bẹ̀rù OLÚWA mi, ẹni tí o ti pèṣè oúnjẹ àti ohun mímu rẹ. Báwo ni ìrísí ì rẹ yóò ṣe burú jù ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ rẹ lọ? Nígbà náà ni èmi yóò fi orí mi wéwu lọ́dọ̀ ọba.”