Daniel 1:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ tẹ Jehoiakimu ọba Juda. Nebukadinesari kó ninu àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun lọ sí ilẹ̀ Ṣinari, ó sì kó wọn sinu ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé oriṣa rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si fi Jehoiakimu, ọba Juda le e lọwọ, pẹlu apakan ohun-elo ile Ọlọrun, ti o kó lọ si ilẹ Ṣinari, si ile oriṣa rẹ̀: o si kó ohun-elo na wá sinu ile-iṣura oriṣa rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì fa Jéhóíákímù ọba Júdà lé e lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó lọ sí ilé òrìṣà ní Bábílónì, sí inú ilé ìṣúra òrìṣà a rẹ̀.