Daniel 1:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ pé kí ó lọ sí ààrin àwọn ọmọ ọba ati àwọn eniyan pataki pataki ninu àwọn ọmọ Israẹli,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wi fun Aṣpenasi, olori awọn iwẹfa rẹ̀, pe, ki o mu awọn kan wá ninu awọn ọmọ Israeli, ninu iru-ọmọ ọba, ati ti awọn ijoye;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Áṣípénásì, olórí àwọn ìwẹ̀fà ààfin rẹ̀ pé, kí ó mú nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n wá láti ìdílé ọba àti lára àwọn tí ó wá láti ilé ọlá.