Daniel 10:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹnìkan tí ó dàbí eniyan wá, ó fi ọwọ́ kàn mí ní ètè; ẹnu mi bá yà, mo sì sọ̀rọ̀. Mo sọ fún ẹni tí ó dúró tì mí pé, “Olúwa mi, gbogbo ara ni ó wó mi, nítorí ìran tí mo rí, ó sì ti rẹ̀ mí patapata.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wò o, ẹnikan ti jijọ rẹ̀ dabi ti awọn ọmọ enia fi ọwọ kan ète mi: nigbana ni mo ya ẹnu mi, mo si fọhùn, mo si wi fun ẹniti o duro tì mi pe, oluwa mi, niti iran na, irora mi pada sinu mi, emi kò si lagbara mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, ni ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kan ètè mi, mo la ẹnu mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ọ̀rọ̀, mo sọ fún ẹni tí ó dúró níwájú mi, “Ìrònú sì mú mi, nítorí ìran náà, OLÚWA mi, n kò sì ní okun.