Daniel 11:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní àkókò náà, ọ̀pọ̀ eniyan yóo dìde sí ọba Ijipti; àwọn oníjàgídíjàgan láàrin àwọn eniyan rẹ̀ yóo dìde kí ìran yìí lè ṣẹ; ṣugbọn wọn kò ní borí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li akoko wọnni li ọ̀pọlọpọ yio si dide si ọba gusu; awọn ọlọ̀tẹ ninu awọn enia rẹ̀ yio si gbé ara wọn ga lati fi ẹsẹ iran na mulẹ pẹlu: ṣugbọn nwọn o ṣubu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní àkókò ìgbà náà, ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò dìde sí ọba Gúṣù. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò ṣọ̀tẹ̀ ní ìmúṣẹ ìran náà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí.