Daniel 11:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba Siria yóo wá dóti ìlú olódi kan, yóo sì gbà á. Àwọn ọmọ ogun Ijipti kò ní lágbára láti dojú ìjà kọ ọ́, àwọn akikanju wọn pàápàá kò ní lágbára mọ́ láti jagun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li ọba ariwa yio si wá, yio si mọdi, yio si gbà ilu olodi; apá ogun ọba gusu kì yio le duro, ati awọn ayanfẹ enia rẹ̀, bẹ̃ni kì yio si agbara lati da a duro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ọba àríwá yóò wá yóò sì gbé ogun tìí, yóò sì kó ìlú olódi. Ogun ọba Gúṣù kò ní ní agbára láti kọjú ìjà sí i; Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọ̀wọ́ ogun tó dára jù kò ní ní agbára láti dúró.