Daniel 11:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ọba Siria yóo múra láti wá pẹlu gbogbo agbára ìjọba rẹ̀, yóo bá ọba Ijipti dá majẹmu alaafia, yóo sì mú majẹmu náà ṣẹ. Yóo fi ọmọbinrin rẹ̀ fún ọba Ijipti ní aya, kí ó lè ṣẹgun ọba Ijipti. Ṣugbọn yóo kùnà ninu ète rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On o si gbé oju rẹ̀ soke lati wọ̀ ọ nipa agbara gbogbo ijọba rẹ̀, yio si ba a dá majẹmu, bẹ̃ni yio ṣe; on o si fi ọmọbinrin awọn obinrin fun u, lati bà a jẹ: ṣugbọn on kì yio duro, bẹ̃ni kì yio si ṣe tirẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò pinnu láti wá pẹ̀lú agbára ìjọba rẹ̀, yóò sì ní májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú ọba Gúṣù yóò sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún-un láti fẹ́ ẹ ní ìyàwó nítorí kí ó lè gba ìjọba, ṣùgbọ́n ète rẹ̀ yìí kì yóò ṣiṣẹ tàbí se ìrànlọ́wọ́ fún-un.