Daniel 11:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, yóo bá àwọn orílẹ̀-èdè ati àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní etíkun jà, yóo sì ṣẹgun ọpọlọpọ wọn. Ṣugbọn olórí-ogun kan yóo ṣẹgun rẹ̀, yóo sì pa òun náà run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin eyi, yio kọ oju rẹ̀ si erekuṣu wọnni, yio si gbà ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn balogun kan fun ara rẹ̀, yio fi opin si ẹ̀gan rẹ̀: ati nipò eyi, yio mu ẹ̀gan rẹ̀ pada wá sori ara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni yóò yí ara padà sí ilẹ̀ etí òkun, yóò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n aláṣẹ kan yóò mú òpin bá àfojúdi rẹ̀, yóò sì yí àfojúdi rẹ̀ padà sí orí i rẹ̀.