Daniel 11:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nisinsinyii, n óo fi òtítọ́ hàn ọ́.” Angẹli náà tún ní, “Àwọn ọba mẹta ni yóo jẹ sí i ní Pasia; ẹkẹrin yóo ní ọrọ̀ pupọ ju gbogbo àwọn yòókù lọ; nígbà tí ó bá sì ti ipa ọrọ̀ rẹ̀ di alágbára tán, yóo ti gbogbo eniyan nídìí láti bá ìjọba Giriki jagun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi li emi o fi otitọ hàn ọ, Kiyesi i, ọba mẹta pẹlu ni yio dide ni Persia; ẹkẹrin yio si ṣe ọlọrọ̀ jù gbogbo wọn lọ: ati nipa agbara rẹ̀ ni yio fi fi ọrọ̀ rú gbogbo wọn soke si ijọba Hellene.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ìsinsìnyí, mo sọ òtítọ́ fún ọ ọba mẹ́ta yóò dìde sí i ní Páṣíà, àti ẹ̀kẹrin tí yóò jẹ́ ọlọ́rọ̀ ju gbogbo wọn lọ. Tí ó bá ti di alágbára nípa ọrọ̀ rẹ̀, yóò sì ru gbogbo wọn sókè lòdì sí ìjọba Gíríkì.