Daniel 11:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ọba mìíràn yóo jẹ lẹ́yìn rẹ̀, yóo sì rán agbowóopá kan kí ó máa gba owó-odè kiri ní gbogbo ìjọba rẹ̀; ní kò pẹ́ kò jìnnà, a óo pa ọba náà, ṣugbọn kò ní jẹ́ ní gbangba tabi lójú ogun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ẹnikan yio dide ni ipò rẹ̀ ti yio mu agbowode kan rekọja ninu ogo ijọba (ilẹ Juda): ṣugbọn niwọn ijọ melokan li a o si pa a run, kì yio ṣe nipa ibinu tabi loju ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Arọ́pò rẹ̀ yóò rán agbowó orí kan jáde láti fi ìdí ipò ọlá ọba múlẹ̀ ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n ọdún díẹ̀, a ó pa á run, kì yóò jẹ́ nípa ìbínú tàbí nínú ogun.