Daniel 11:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Angẹli náà tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé, “Ọba tí yóo tún jẹ ní Siria yóo jẹ́ ọba burúkú. Kì í ṣe òun ni oyè yóo tọ́ sí, ṣugbọn yóo dé lójijì, yóo sì fi àrékérekè gba ìjọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni ipò rẹ̀ li enia lasan kan yio dide, ẹniti nwọn kì yio fi ọlá ọba fun: ṣugbọn yio wá lojiji, yio si fi arekereke gbà ijọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹni tí kò níláárí kan yóò rọ́pò rẹ̀, ẹni tí a kò tí ì fi ọlá ọba fún rí. Yóò sì gbógun sí ìjọba nígbà tí ọkàn àwọn ènìyàn balẹ̀ láìbẹ̀rù, yóò sì gbà á pẹ̀lú àrékérekè.