Daniel 11:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lójijì yóo wá sí àwọn ibi tí ó ní ọrọ̀ jùlọ ní agbègbè náà, yóo máa ṣe ohun tí àwọn baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí. Yóo máa pín ìkógun rẹ̀ fún wọn. Yóo máa wá ọ̀nà ti yóo fi gba àwọn ìlú olódi; ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀ ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si wọ̀ gbogbo ibi igberiko ọlọra; yio si ṣe ohun ti awọn baba rẹ̀ kò ṣe ri, tabi awọn baba nla rẹ̀; yio si fọn ikogun, ìfa, ati ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ ká si ãrin wọn: yio si gbèro tẹlẹ si ilu olodi, ani titi akokò kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn agbègbè tí ó lọ́rọ̀ gidigidi wà láìbẹ̀rù ni yóò gbógun tì wọ́n, yóò ṣe ohun tí baba rẹ̀ tàbí baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí, yóò pín ìkógún ẹrù àti ọrọ̀ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn in rẹ̀. Yóò pète àti bi àwọn ìlú olódi ṣubú, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀ ni.