Daniel 11:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Yóo fi gbogbo agbára ati ìgboyà rẹ̀ gbé ogun ńlá ti ọba Ijipti; ọba Ijipti náà yóo gbé ogun ńlá tì í, ṣugbọn kò ní lè dúró níwájú ọba Ijipti nítorí pé wọn yóo dìtẹ̀ mọ́ ọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si rú agbara ati igboya rẹ̀ soke si ọba gusu ti on ti ogun nla; a o si rú ọba gusu soke si ija pẹlu ogun nlanla ati alagbara pupọ; ṣugbọn on kì yio le duro: nitori nwọn o gba èro tẹlẹ si i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Pẹ̀lú ogun púpọ̀, yóò sì ru agbára rẹ̀ àti ìgboyà rẹ̀ ṣókè sí ọba Gúṣù. Ọba Gúṣù yóò dìde ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun tí ó lágbára gidigidi, ṣùgbọ́n kò ní leè dúró, nítorí ọ̀tẹ̀ tí ó gbérò sí i.