Daniel 11:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọba mejeeji ni yóo pinnu láti hùwà àrékérekè, wọn ó sì máa purọ́ tan ara wọn jẹ níbi tí wọ́n ti jọ ń jẹun; ṣugbọn òfo ni ọgbọ́n àrékérekè wọn yóo já sí; nítorí pé òpin wọn yóo dé ní àkókò tí a ti pinnu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkàn awọn ọba mejeji wọnyi ni yio wà lati ṣe buburu, nwọn o si mã sọ̀rọ eké lori tabili kan, ṣugbọn kì yio jẹ rere; nitoripe opin yio wà li akokò ti a pinnu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọba méjèèjì, ọkàn wọn tẹ̀ sí búburú, wọn yóò jókòó lórí tábìlì kan, wọn yóò máa parọ́ sí ara wọn, ṣùgbọ́n kò ní yọrí sí nǹkan kan nítorí òpin yóò wá ní àsìkò tí a yàn.