Daniel 11:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nítorí pé, àwọn ọmọ ogun Kitimu tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ ojú omi yóo gbógun tì í. “Ẹ̀rù yóo bà á, yóo sì sá pada, yóo fi ibinu ńlá gbógun ti majẹmu mímọ́ Ọlọrun ati Israẹli, yóo sì máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn tí wọ́n ti kọ majẹmu náà sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe ọkọ̀ awọn ara Kittimu yio tọ̀ ọ wá, nitorina ni yio ṣe dãmu, yio si yipada, yio si ni ibinu si majẹmu mimọ́ nì; bẹ̃ni yio ṣe; ani on o yipada, yio si tun ni idapọ pẹlu awọn ti o kọ̀ majẹmu mimọ́ na silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé, ọkọ̀ ojú omi àwọn ilẹ̀ etídò ìwọ̀-oòrùn yóò ta kòó, ọkàn rẹ̀ yóò sì pámi. Nígbà náà, ni yóò padà, yóò sì bínú sí májẹ̀mu mímọ́, yóò sì padà, yóò sì fi ojú rere hàn sí àwọn tí ó kọ májẹ̀mu mímọ́ náà.