Daniel 11:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Pẹlu ẹ̀tàn, ọba yìí yóo mú àwọn tí wọ́n kọ majẹmu náà sílẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́; ṣugbọn àwọn tí wọ́n mọ Ọlọrun yóo dúró ṣinṣin, wọn óo sì ṣe ẹ̀tọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati iru awọn ti nṣe buburu si majẹmu nì ni yio fi ọ̀rọ ipọnni mu ṣọ̀tẹ: ṣugbọn awọn enia ti o mọ̀ Ọlọrun yio mu ọkàn le, nwọn o si ma ṣe iṣẹ agbara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú ẹ̀tàn ni yóò bá àwọn tí ó ba májẹ̀mú jẹ́, ṣùgbọ́n, àwọn tí ó mọ Ọlọ́run wọn yóò jẹ́ alágbára. Wọn yóò sì kọjú ìjà sí i.