Daniel 11:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ohun tí ó bá wu ọba náà ni yóo máa ṣe; yóo gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo oriṣa lọ, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo máa sọ̀rọ̀ tó lòdì sí Ọlọrun àwọn ọlọrun, yóo sì bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i títí ọjọ́ ibinu tí a dá fún un yóo fi pé; nítorí pé ohun tí Ọlọrun ti pinnu yóo ṣẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba na yio si ma ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀; on o si gbé ara rẹ̀ ga, yio si gbéra rẹ̀ ga jù gbogbo ọlọrun lọ, yio si ma sọ̀rọ ohun iyanu si Ọlọrun awọn ọlọrun, yio si ma ṣe rere titi a o fi pari ibinu: nitori a o mu eyi ti a ti pinnu rẹ̀ ṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọba yóò ṣe bí ó ti wù ú yóò sì gbé ara rẹ̀ ga, ju gbogbo òrìṣà lọ, yóò máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò-ṣe-é-gbọ́-létí sí Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run, a yóò sì máa yege títí àkókò ìbínú yóò fi parí, nítorí ohun tí a ti pinnu yóò ṣẹlẹ̀.