Daniel 11:37 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kò ní náání oriṣa tí àwọn baba rẹ̀ ń sìn, kò sì ní bìkítà fún èyí tí àwọn obinrin fẹ́ràn; kò ní bìkítà fún oriṣa kankan, nítorí pé yóo gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo wọn lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li on kì yio si kà Ọlọrun awọn baba rẹ̀ si, tabi ifẹ awọn obinrin, on kì yio si kà ọlọrun kan si: nitoriti yio gbé ara rẹ̀ ga jù ẹni gbogbo lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun kò ní ka òrìṣà àwọn baba rẹ̀ sí tàbí èyí tí àwọn fẹ́, òun kò ní ka ìkankan sí, ṣùgbọ́n yóò gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo wọn lọ.