Daniel 11:38 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dípò gbogbo wọn, yóo máa bọ oriṣa àwọn ìlú olódi; oriṣa tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ rí ni yóo máa sìn, yóo máa fún un ní wúrà ati fadaka, òkúta iyebíye ati àwọn ẹ̀bùn olówó iyebíye.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ni ipò rẹ̀, yio ma bu ọlá fun ọlọrun awọn ilu olodi, ani ọlọrun kan ti awọn baba rẹ̀ kò mọ̀ ri ni yio ma fi wura, ati fadaka, ati okuta iyebiye, ati ohun daradara bu ọlá fun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n dípò wọn, yóò bu ọlá fún òrìṣà àwọn ìlú olódi: òrìṣà tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ ni yóò bu ọlá fún pẹ̀lú wúrà àti fàdákà, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti ẹ̀bùn tí ó lówó lórí.