Daniel 11:40 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà tí àkókò ìkẹyìn bá dé, ọba ilẹ̀ Ijipti yóo gbógun tì í; ṣugbọn ọba Siria yóo gbógun tì í bí ìjì líle, pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi. Yóo kọlu àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri yóo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ lọ bí àgbàrá òjò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li akokò opin, ọba gusu yio kàn a, ọba ariwa yio si fi kẹkẹ́, ati ẹlẹṣin, ati ọ̀pọlọpọ ọkọ̀, kọ lu u bi afẹyika-ìji: on o si wọ̀ ilẹ wọnni yio si bò wọn mọlẹ, yio si rekọja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ìgbà ìkẹyìn, ọba Gúṣù yóò gbé ogun de sí i, ọba àríwá yóò sì jáde bí ìjì láti kọ lù ú pẹ̀lú u kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́ṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ ojú omi. Yóò gbógun wọ orílẹ̀ èdè púpọ̀, yóò sì gbá wọn mọ́lẹ̀ bí ìkún omi.