Daniel 11:41 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yóo wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà. Ẹgbẹẹgbẹrun yóo ṣubú, ṣugbọn a óo gba Edomu ati Moabu lọ́wọ́ rẹ̀, ati ibi tí ó ṣe pataki jùlọ ninu ilẹ̀ àwọn ará Amoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si wọ̀ ilẹ ologo nì pẹlu, ọ̀pọlọpọ li a o si bì ṣubu: ṣugbọn awọn wọnyi ni yio si bọ lọwọ rẹ̀, ani Edomu, ati Moabu, ati olori awọn ọmọ Ammoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì tún gbógun ti ilẹ̀ ológo náà pẹ̀lú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè yóò ṣubú, ṣùgbọ́n Édómù, Móábù àti àwọn olórí Ámónì yóò bọ́ lọ́wọ́ ọ rẹ̀.