Daniel 11:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ọba Ijipti ní ìhà gúsù yóo lágbára, ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo lágbára jù ú lọ, ìjọba rẹ̀ yóo sì tóbi ju ti ọba lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba iha gusu yio si lagbara; ṣugbọn ọkan ninu awọn balogun rẹ̀, on o si lagbara jù u lọ, yio si jọba, ijọba rẹ̀ yio jẹ ijọba nla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọba ìhà Gúṣù yóò di alágbára ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ rẹ̀ yóò di alágbára jùú lọ, yóò sì ṣe àkóso ìjọba rẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá.