Daniel 11:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ yóo jọba ní ipò rẹ̀, yóo wá pẹlu ogun, yóo wọ ìlú olódi ọba Siria, yóo bá wọn jagun, yóo sì ṣẹgun wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ninu ẹka gbòngbo rẹ̀ li ẹnikan yio dide ni ipò rẹ̀, ẹniti yio wá pẹlu ogun, yio si wọ̀ ilu-olodi ọba ariwa, yio si ba wọn ṣe, yio si bori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọ̀kan lára àwọn ìdílé e rẹ̀, ọmọbìnrin ọba Gúṣù yóò dìde láti gba ipò o rẹ̀. Yóò sì kọ lu ogun ọba àríwá, yóò sì wọ́ odi alágbára; yóò bá wọn jà yóò sì borí.