Daniel 12:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọ̀pọ̀ ninu àwọn tí ó ti kú, tí wọ́n ti sin ni yóo jí dìde, àwọn kan óo jí sí ìyè ainipẹkun, àwọn mìíràn óo sì jí sí ìtìjú ati ẹ̀sín ainipẹkun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ọ̀pọlọpọ ninu awọn ti o sùn ninu erupẹ ilẹ ni yio ji, awọn miran si ìye ainipẹkun, ati awọn miran si itiju ati ẹ̀gan ainipẹkun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò jí: àwọn mìíràn sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn tókù sí ìtìjú àti sí ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun.