Daniel 12:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní, “Ṣugbọn ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé, kí o sì fi èdìdì dì í títí di àkókò ìkẹyìn. Nítorí àwọn eniyan yóo máa sá síhìn-ín, sá sọ́hùn-ún, ìmọ̀ yóo sì pọ̀ sí i.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn iwọ, Danieli sé ọ̀rọ na mọhun, ki o si fi edidi di iwe na, titi fi di igba ikẹhin: ọ̀pọlọpọ ni yio ma wadi rẹ̀, ìmọ yio si di pupọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ìwọ Dáníẹ́lì, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.”