Daniel 2:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní tèmi, kì í ṣe pé mo gbọ́n ju àwọn yòókù lọ ni a ṣe fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí hàn mí, bíkòṣe pé kí ọba lè mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kí òye ohun tí ó ń rò sì lè yé e.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi o ṣe temi ni, a kò fi aṣiri yi hàn fun mi nitori ọgbọ́n ti emi ni jù ẹni alãye kan lọ, ṣugbọn nitori ki a le fi itumọ na hàn fun ọba, ati ki iwọ ki o le mọ̀ èro ọkàn rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbn fún èmi, a fi àsírí yìí hàn mí, kì í ṣe pé mo ní ọgbọ́n tí ó pọ̀ ju ti alààyè kankan lọ, ṣùgbọ́n nítorí kí ọba lè mọ ìtumọ̀ àlá àti kí ó lè mọ ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ̀.