Daniel 2:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí o ti ń wò ó, òkúta kan là, ó sì ré bọ́ láti òkè, ó bá ère náà ní ẹsẹ̀ mejeeji tí ó jẹ́ àdàlú irin ati amọ̀, mejeeji sì fọ́ túútúú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ri titi okuta kan fi wá laisi ọwọ, o si kọlu ere na lẹsẹ rẹ̀, ti iṣe ti irin ati amọ̀, o si fọ́ wọn tũtu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó ṣe ń wò, òkúta kan wá, tí kò wá láti ọwọ́ ẹnìkankan. Ó kọlu ère náà ní àtẹ́lẹṣẹ̀ irin àti amọ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́ẹ́wẹ́.