Daniel 2:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́sẹ̀kan náà òkúta yìí bá fọ́ gbogbo ère náà, ati irin, ati amọ̀, ati idẹ, ati fadaka ati wúrà, ó rún gbogbo wọn wómúwómú, títí wọ́n fi dàbí ìyàngbò ní ibi ìpakà. Lẹ́yìn náà, afẹ́fẹ́ fẹ́ wọn lọ, a kò sì rí wọn mọ́ rárá. Òkúta tí ó kọlu ère náà di òkè ńlá, ó sì bo gbogbo ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li a si fọ irin, amọ̀, idẹ, fadaka ati wura pọ̀ tũtu, o si dabi iyangbo ipaka nigba ẹ̀run; afẹfẹ si gbá wọn lọ, ti a kò si ri ibi kan fun wọn mọ́: okuta ti o si fọ ere na si di òke nla, o si kún gbogbo aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni irin, amọ̀, idẹ, fàdákà àti wúrà fọ́ sí wẹ́wẹ́ lẹ́ṣẹ̀ kan náà, ó sì dàbí ìyàngbò tí a fẹ́ kúrò lórí ọkà ní àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn. Afẹ́fẹ́ gbé gbogbo rẹ̀ lọ láì ṣẹ́ku ọ̀kan mọ́, òkúta tí ó fọ́ ère náà sì di òkè ńlá, ó sì gba gbogbo ayé.