Daniel 2:47 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba sọ fún Daniẹli pé, “Láìsí àní àní, Ọlọrun rẹ ni Ọlọrun àwọn ọlọrun, ati OLUWA àwọn ọba, òun níí fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ han eniyan, nítorí pé àṣírí ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí gan-an ni o sọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba da Danieli lohùn, o si wipe, Lõtọ ni, pe Ọlọrun nyin li Ọlọrun awọn ọlọrun ati Oluwa awọn ọba, ati olufihàn gbogbo aṣiri, nitori ti iwọ le fi aṣiri yi hàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba wí fún Dáníẹ́lì pé, “Dájúdájú Ọlọ́run rẹ ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti OLÚWA àwọn ọba gbogbo àti olùfihàn àwọn àsírí, nítorí tí ìwọ lè fi àsírí yìí hàn.”