Daniel 3:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nisinsinyii, bí ẹ bá ti gbọ́ ìró ipè, fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, tí ẹ bá wólẹ̀, tí ẹ sì sin ère tí mo ti yá, ó dára, ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò wólẹ̀, wọn óo gbe yín sọ sinu adágún iná ìléru. Kò sì sí ọlọrun náà tí ó lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ bi ẹnyin ba mura pe, li akokò ti o wù ki o ṣe ti ẹnyin ba gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ti ẹ ba wolẹ ti ẹ ba si tẹriba fun ere wura ti mo yá, yio ṣe gẹgẹ; ṣugbọn bi ẹnyin kò ba tẹriba, a o gbé nyin ni wakati kanna sọ si ãrin iná ileru ti njo; ta li Ọlọrun na ti yio si gbà nyin kuro li ọwọ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìsinsìnyìí, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókun, ìpè àti onírúurú orin, bí ẹ̀yin bá ṣetan láti wólẹ̀ kí ẹ̀yin fi orí balẹ̀ fún ère tí mo gbé kalẹ̀ ó dára. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yìn bá kọ̀ láti sìn ín, lójúkan náà ni a ó gbé e yín jù sínú iná ìléru. Ǹjẹ́, ta ni Ọlọ́run náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”