Daniel 3:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí bí àṣẹ ọba ti le tó, ati bí adágún iná náà ti gbóná tó, ahọ́n iná tí ń jó bùlàbùlà jó àwọn tí wọ́n gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sinu rẹ̀ ní àjópa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bi aṣẹ ọba ti le to, ati bi ileru na si ti gboná gidigidi to, ọwọ iná na si pa awọn ọkunrin ti o gbé Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí bí àsẹ ọba ṣe le tó, tí iná ìléru náà sì gbóná, ọwọ́ iná pa àwọn ọmọ ogun tí wọ́n mú Sádírákì, Mésákì àti Àbẹ́dinígò lọ.