Daniel 3:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nebukadinesari ọba bá lọ sí ẹnu ọ̀nà adágún iná náà, ó kígbe pé, “Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, ẹ̀yin iranṣẹ Ọlọrun alààyè, ẹ jáde wá!” Wọ́n bá jáde kúrò ninu iná lẹsẹkẹsẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Nebukadnessari sunmọ ẹnu-ọ̀na ileru na o dahùn o si wipe, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ẹnyin iranṣẹ Ọlọrun Ọga-ogo, ẹ jade ki ẹ si wá. Nigbana ni Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, jade lati ãrin iná na wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, ni Nebukadinésárì dé ẹnu ọ̀nà iná ìléru, ó sì kígbe pé, “Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀gá ògo, ẹ jáde, ẹ wá níbi!” Nígbà náà ni Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò jáde láti inú iná.