Daniel 3:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, mo pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, tabi orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà tí ó bá sọ̀rọ̀ àbùkù sí Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati ti Abedinego, fífà ni a ó fa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ya ní tapá-titan, a ó sì sọ ilé rẹ̀ di ahoro; nítorí kò sí ọlọrun mìíràn tí ó lè gbani là bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, emi paṣẹ pe, olukulùku enia, orilẹ, ati ède, ti o ba sọ ọ̀rọ odi si Ọlọrun Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, a o ke e wẹwẹ, a o si sọ ile rẹ̀ di àtan: nitori kò si Ọlọrun miran ti o le gbà ni là bi iru eyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, mo pa àṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, orílẹ̀ èdè tàbí èdè kan tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò kí a gé wọn sí wẹ́wẹ́ kí a sì sọ ilé e wọn di ààtàn; nítorí kò sí Ọlọ́run mìíràn tí ó lè gba ènìyàn bí irú èyí.”