Daniel 4:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Olùṣọ́ náà pàṣẹ pé kí á fi gbòǹgbò igi náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀; ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, dájúdájú, o óo tún pada wá jọba, nígbà tí o bá gbà pé Ọlọrun ni ọba gbogbo ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gẹgẹ bi nwọn si ti paṣẹ pe ki nwọn ki o fi kukute gbòngbo igi na silẹ, ijọba rẹ yio jẹ tirẹ, lẹhin igbati o ba ti mọ̀ pe, ọrun ni iṣe olori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọ́n ṣe pàṣẹ pé kí wọn fi kùkùté àti gbòǹgbò igi náà sílẹ̀, èyí túmọ̀ sí wí pé a ó dá ìjọba rẹ padà fún ọ lẹ́yìn ìgbà tí o bá ti mọ̀ wí pé, Ọ̀run jọba.