Daniel 4:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
a óo lé ọ kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo máa bá àwọn ẹranko gbé, o óo sì máa jẹ koríko bíi mààlúù fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé, Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ati pé ẹni tí ó bá wù ú ní í máa gbé e lé lọ́wọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A o si le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ: nwọn o si mu ọ jẹ koriko bi malu, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe, Ọga-ogo ni iṣe olori ninu ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A ó lé ọ kúrò láàrin àwọn ènìyàn, ìwọ yóò sì lọ máa gbé àárin àwọn ẹranko igbó; ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìgbà méje yóò kọjá lórí i rẹ títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé, Ọ̀gá Ògo jọba lórí ìjọba ènìyàn àti pé ó ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.”