Daniel 5:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹnìkan ń bẹ ní ìjọba rẹ tí ó ní ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ninu. Ní àkókò baba rẹ, a rí ìmọ́lẹ̀, ìmọ̀, ati ọgbọ́n bíi ti Ọlọrun ninu rẹ̀. Òun ni baba rẹ, Nebukadinesari ọba, fi ṣe olórí gbogbo àwọn pidánpidán, àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn Kalidea ati àwọn awòràwọ̀;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin kan mbẹ ni ijọba rẹ, lara ẹniti ẹmi Ọlọrun mimọ́ wà; ati li ọjọ baba rẹ, a ri imọlẹ, ati oye, ati ọgbọ́n gẹgẹ bi ọgbọ́n Ọlọrun lara rẹ̀: ẹniti Nebukadnessari ọba, baba rẹ, ani ọba, baba rẹ fi ṣe olori awọn amoye, ọlọgbọ́n, awọn Kaldea, ti awọn alafọṣẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin kan wà ní ìjọba à rẹ, ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run, mímọ́ ń gbé inú un rẹ̀. Ní ìgbà ayé e bàbá à rẹ, òun ni ó ní ojú inú, òye àti ìmọ̀ bí i ti Ọlọ́run òun ni ọba Nebukadinéṣárì, bàbá rẹ̀ fi jẹ olórí àwọn onídán, awòràwọ̀, apògèdè àti aláfọ̀ṣẹ.